1. Oluwa mbo; aye yo mi, Oke y‘o sidi n‘ipo won; At‘ irawo oju orun, Y‘o mu imole won kuro. 2. Oluwa mbo; bakanna ko...
1. Oluwa mbo; aye yo mi,
Oke y‘o sidi n‘ipo won;
At‘ irawo oju orun,
Y‘o mu imole won kuro.
2. Oluwa mbo; bakanna ko
Bi o ti wa n‘irele ri;
Odo-agutan ti a pa,
Eni-iya ti o si ku.
3. Oluwa mbo; li eru nla,
L‘owo ina pelu ija
L‘or‘ iye apa Kerubu,
Mbo, Onidajo araye
4. Eyi ha li eniti nrin,
Bi ero l‘opopo aye?
Ti a se ‘nunibini si?
A! Eni ti a pa l‘eyi?
5. Ika b‘e wo ‘nu apata,
B‘e wo ‘nu iho, lasan ni;
Sugbon igbagbo t‘o segun,
Y‘o korin pe, Oluwa de.
Amin
No comments