FALSE

Page Nav

HIDE
GRID_STYLE
FALSE
TRUE

Latest Update:

latest

Adsense

Popular Yoruba Hymns 2

Contents 1. Elese e yipada  2. Aye si mbe! Ile Od’agutan  3. Wa s’odo Jesu, mase duro  4. Bi Kristi’ ti da okan mi nde  5. Bi mo ti ri, ...

Contents
1. Elese e yipada 
2. Aye si mbe! Ile Od’agutan 

3. Wa s’odo Jesu, mase duro 

4. Bi Kristi’ ti da okan mi nde 

5. Bi mo ti ri, lai s’awawi 

6. Olugbala gb’ohun mi 

7. Oluwa emi sa ti gb’ohun Re 

8. Isun kan wa to kun f’eje 

9. Okan mi nyo ninu Oluwa 

10. Ore ofe ohun 

11. Irapada itan iyanu 

12. Aleluya, Ija d’opin ogun si tan 

13. B’elese s’owo po 

14. Mo mo p'Oludande mi mbe 

15. Mi si mi, Olorun 

16. Itan iyanu t’ife 

17. Jesu y’o gba elese 

18. E yo n’nu Oluwa e yo 

19. A segun ati ajogun ni a je 


Elese e yipada
1. Elese e yipada,
Ese ti e o fi ku ?
Eleda yin ni mbere
To fe ki e ba On gbe
Oran nla ni O mbi yin
Ise owo Re ni yin
A ! eyin alailope
Ese t’eo ko ‘fe Re ?
2. Elese e yi pada
Ese ti e o fi ku ?
Olugbala ni mbere
Eni t’O gb’emi yin la
Iku Re y’o j’asan bi ?
E o tun kan mo ‘gi bi ?
Eni ‘rapada ese
Te o gan or’ofe Re ?
3. Elese e yi pada
Ese ti e o fi ku ?
Emi mimo ni mbere
Ti nf’ojo gbogbo ro yin
E ki o ha gb’ore Re ?
E o ko iye sibe ?
Ati nwa yin pe ese
T’e mbi Olorun ninu ?
4. Iyemeji ha nse yin
Pe ife ni Olorun
E ki o ha gboro Re ?
K’e gba ileri Re gbo ?
W’Oluwa lodo yin
Jesu sun, w’omije Re
Eje Re pelu nke pe
Ese ti e o fi ku ?. Amin.

Aye si mbe ! ile Od’agutan
1. Aye si mbe ! ile Od’agutan
Ewa ogo re npe o pe « ma bo »
Wole, wole, wole nisisiyi
2. Ojo lo tan, orun si fere wo
Okunkun de tan, ‘mole nkoja lo
Wole, wole, wole nisisiyi
3. Ile iyawo na kun fun ase
Wole, wole to oko ‘yawo lo
Wole, wole, wole nisisiyi
4. O nkun ! o nkun ! ile ayo na nkun
Yara ! mase pe ko kun ju fun O !
Wole,wole,wole nisisiyi.
5. Aye si mbe ilekun si sile
Ilekun ife, iwo ko pe ju
Wole, wole, wole nisisiyi
6. Wole, wole ! tire ni ase na
Wa gb’ebun ‘fe ayeraye lofe !
Wole, wole wole nisisiyi.
7. Kiki ayo l’o wa nibe, wole !
Awon angeli npe o fun ade
Wole, wole, wole nisisiyi.
8. L’ohun rara n’ipe ife na ndun !
Wa ma jafara, wole, ase na !
Wole, wole, wole nisisiyi
9. K’ile to su, ilekun na le ti
‘gba na o k’abamo ! « o se ! o se ! »
O se, o se, ko s’aye mo o se !. Amin.

Wa s’odo Jesu, mase duro
1. Wa s’odo Jesu, mase duro
L’oro Re l’o ti fona han wa
O duro li arin wa loni
O nwi pele pe wa !
Ipade wa yio je ayo
Gb’okan wa ba bo lowo ese
T’a o si wa pelu Re Jesu
N’ile ayeraye
2. Jek’omode wa ! E gb’ohun Re
Jek’okan gbogbo kun fun ayo
K’a si yan Jesu l’ayanfe wa
E ma duro, e wa.
3. Ranti p’O wa pelu wa loni
F’eti s’ofin Re, k’o si pamo
Gbo b’ohun Re ti nwi pele pe
Eyin omo Mi wa.

Bi Kristi’ ti da okan mi nde
1. Bi Kristi’ ti da okan mi nde
Aye mi ti dabi orun
Larin ‘banuje at’aro
Ayo ni lati mo Jesu
Aleluya ! ayo l’o je
Pe mo ti ri ‘dariji gba
Ibikibi ti mo ba wa
Ko s’ewu, Jesu wa nibe
2. Mo ti r ope orun jina
Sugbon nigbati Jesu de
L’orun ti de ‘nu okan mi
Nibe ni y’o si wa titi
3. Nibo l’a ko le gbe l’aye
L’o r’oke tabi petele
L’ahere tabi agbala
Ko s’ewu, Jesu wa nibe. Amin.

Bi mo ti ri, lai s’awawi
1. Bi mo ti ri, lai s’awawi
Sugbon nitori eje Re
B’o si ti pe mi pe ki nwa
Olugbala, mo de.
2. Bi mo ti ri, laiduro pe
Mo fe k ‘okan mi mo toto
S’odo Re to le we mi mo
Olugbala, mo de
3. Bi mo ti ri, b’o tile je
Ija l’ode, ija ninu
Eru l’ode, eru ninu
Olugbala, mo de
4. Bi mo ti ri, osi are
Mo si nwa imularada
Iwo le s’awotan mi
Olugbala, mo de.
5. Bi mo ti ri ‘wo o gba mi
‘wo o gba mi, t’owo t’ese
‘tori mo gba ‘leri Re gbo
Olugbala, mo de.
6. Bi mo ti ri ife Tire
L’o sete mi patapata
Mo di Tire, Tire nikan
Olugbala, mo de.
7. Bi mo ti ri, n’nu ‘fe nla ni
T’o fi titobi Re han mi
Nihin yi ati ni oke
Olugbala, mo de. Amin.

Olugbala, gb’ohun mi
1. Olugbala, gb’ohun mi
Gb’ohun mi, gb’ohun mi
Mo wa s’odo Re, gba mi
Nibi agbelebu
Emi se sugbon O ku
Iwo ku, iwo ku
Fi anu Re pa mi mo
Nibi agbelebu
Oluwa, jo gba mi
Nki y’o bi O ninu mo
Alabukun, gba mi
Nibi agbelebu
2. Ese mi po lapoju
Un o bebe, un o bebe
Iwo li Ona iye
Nibi agbelebu
Ore ofe Re t’a gba
L’ofe ni l’ofe ni
F’oju anu Re wo mi
N’ibi agbelebu
3. F’eje mimo Re we mi
Fi we mi fi we mi
Ri mi sinu ibu Re
N’ibi agbelebu
‘gbagbo l’o le fun wa ni
‘dariji ‘dariji
Mo f’igbagbo ro mo o
N’ibi agbelebu. Amin.

Oluwa, emi sa ti gb’ohun Re
1. Oluwa emi sa ti gb’ohun Re
O nso ife Re simi
Sugbon mo fe nde l’apa igbagbo
Ki nle tubo sun mo o
Fa mi mora, mora, Oluwa
Sib’agbelebu t’O ku
Fa mi mora, mora, mora Oluwa
Si b’eje Re t’o n’iye
2. Ya mi si mimo fun ise Tire
Nipa ore-ofe Re
Je ki nfi okan igbagbo w’oke
K’ife mi si je Tire
3. A ! ayo mimo ti wakati kan
Ti mo lo nib’ite Re
‘gba mo ngb’adura si O Olorun
Ti a soro bi ore.
4. Ijinle ife mbe ti nko le mo
Titi un o koja odo
Ayo giga ti emi ko le so
Tit un o fi de ‘simi. Amin.

Isun kan wa to kun f’eje
1. Isun kan wa to kun f’eje
T’o ti ‘ha Jesu yo
Elese mokun ninu re
O bo ninu ebi
2. ‘Gba mo f’igbagbo r’isun na
Ti nsan fun eje Re
Irapada d’orin fun mi
Ti un o ma ko titi
3. Orin t’odun ju eyi lo
Li emi o ma ko
‘Gbati ore-ofe Re ba
Mu mi de odo Re.
4. Mo gbagbo p’o pese fun mi
Bi mo tile s’aiye
Ebun ofe t’a f’eje ra
Ati duru wura
5. Duro t’a t’ow’ Olorun se
Ti ko ni baje lae
Ti ao ma fi yin Baba wa
Oruko Re nikan. Amin.

Okan mi nyo ninu Oluwa
1. Okan mi nyo ninu Oluwa
‘Tori O je iye fun mi
Ohun Re dun pupo lati gbo
Adun ni lati r’oju Re
Emi nyo ninu Re
Emi nyo ninu Re
Gba gbogbo lo fayo kun okan mi
‘Tori emi nyo n’nu Re.
2. O ti pe t’O ti nwa mi kiri
‘gbati mo rin jina s’agbo
O gbe mi w asile l’apa Re
Nibiti papa tutu wa
3. Ire at’anu Re yi mi ka
Or’ofe Re nsan bi odo
Emi Re nto, o si nse ‘tunu
O mba mi lo si ‘bikibi
4. Emi y’o dabi Re ni ‘jo kan
Un o s’eru wuwo mi kale
Titi di ‘gbana un o s’oloto
Ni sise oso f’ade Re. Amin.

Ore ofe ohun
1. Ore ofe ohun
Adun ni l’eti wa
Gbohun gbohun re y’o gba orun kan
Aye y’o gbo pelu
Ore ofe sa
N’igbekele mi
Jesu ku fun araye
O ku fun mi pelu
2. Ore ofe l’o ko
Oruko mi l’orun
L’o fi mi fun Od’agutan
T’O gba iya mi je.
3. Ore ofe to mi
S’ona alafia
O ntoju mi l’ojojumo
Ni irin ajo mi
4. Ore ofe ko mi
Bi a ti ‘gbadura
O pa mi mo titi d’oni
Ko si je ki nsako
5. Je k’ore ofe yi
F’agbara f’okan mi
Ki nle fi gbogbo ipa mi
At’ojo mi fun O. Amin.

IRAPADA ITAN IYANU
1. Irapada ! itan iyanu
Ihin ayo fun gbogbo wa
Jesu ti ra ‘dariji fun wa
O san ‘gbese na lor’igi
A ! elese gba ihin na gbo
Jo gba ihin oto na gbo
Gbeke re le Olugbala re
T’O mu igbala fun o wa
2. O mu wa t’inu ‘ku bo si ‘ye
O si so wa d’om’Olorun
Orisun kan si fun elese
We nin’eje na ko si mo
3. Ese ki y’o le joba wa mo
B’o ti wu ko dan waw o to
Nitori Kristi fi ‘rapada 
Pa ‘gbara ese run fun wa
4. Gba anu t’Olorun fi lo o
Sa wa s’odo Jesu loni
‘Tori y’o gb’enit’o ba t’o wa
Ki yi o si da pada lae. Amin.

Aleluya, Ija d’opin, ogun si tan
1. Ija d’opin ogun si tan
Olugbala jagun molu
Orin ayo lao ma ko – Aleluya
2. Gbogbo ipa n’iku ti lo
Sugbon Kristi f’ogun re ka
Aye ! e ho iho ayo – Aleluya
3. Ojo meta na ti koja
O jinde kuro nin’oku
E f’ogo fun Oluwa wa – Aleluya
4. O d’ewon orun apadi
O silekun orun sile
Ekorin iyin ‘segun Re – Aleluya
5. Jesu, nipa iya t’O je
Gba wa lowo oro iku
K’a le ye ka si ma yin O – Aleluya. Amin.

B’elese s’owo po
1. B’elese s’owo po
Ti won nde s’Oluwa
Dimo si Kristi Re
Lati gan Oba na
B’aye sata
Pelu Esu
Eke ni won
Won nse lasan
2. Olugbala joba
Lori oke Sion
Ase ti Oluwa
Gbe Omo Tire ro
Lati boji
O ni k’O nde
K’O si goke
K’O gba ni la
3. F’eru sin Oluwa
Si bowo f’ase Re
F’ayo wa sodo Re
F’iwariri duro
E kunle fun Un
K’e teriba
So t’ipa Re
Ki Omo na !. Amin.

MO MO P’OLUDANDE MI MBE
1. Mo mo p’Oludande mi mbe
Itunu nla l’eyi fun mi !
O mbe, Eni t’o ku lekan
O mbe, ori iye mi lae.
2. O mbe lati ma bukun mi
O si mbebe fun mi loke
O mbe lati ji mi n’boji
Lati gba mi la titi lae
3. O mbe, Ore korikosun
Ti y’o pa mi mo de opin
O mbe, emi o ma korin
Woli, Alufa, Oba mi
4. O mbe lati pese aye
Y’O si mu mi de be l’ayo
O mbe, ogo f’oruko Re
Jesu okan na titi lae
5. O mbe, ogo f’oruko Re
Olugbala kanna titi
A ! ayo l’oro yi fun mi
« Mo mo p’oludande mi mbe ». Amin

MI SI MI, OLORUN
1. Mi si mi, Olorun
F’emi titun fun mi
Ki nle fe ohun ti O fe
Ki ns’eyi t’O fe se
2. Mi si mi, Olorun
S’okan mi di mimo
K’ife mi on Tire j’okan
L’ero ati n’ise
3. Mi si mi, Olorun
Titi un o di Tire
Ti ara erupe mi yi
Yo tan ‘mole orun
4. Mi si mi, Olorun
Emi ki yo ku lae
Un o ba Ogbe n’iwa pipe
Titi ayeraye. Amin.

ITAN IYANU T’IFE !
1. Itan iyanu t’ife !
So fun mi l’ekan si
Itan iyanu t’ife
E gbe orin na ga !
Awon angeli nroyin re
Awon oluso si gbagbo
Elese, iwo ki yo gbo
Itan iyanu t’ife
Iyanu ! Iyanu ! Iyanu !
Itan iyanu t’ife
2. Itan iyanu t’ife
B’iwo tile sako
Itan iyanu t’ife
Sibe o npe loni
Lat’ori oke kalfari
Lati orisun didun ni
Lati isedale aye
Itan iyanu t’ife
3. Itan iyanu t’ife
Jesu ni isimi
Itan iyanu t’ife
Fun awon oloto
To sun ni ile nla orun
Pel’awon to saju wa lo
Won nko orin ayo orun
Itan iyanu t’ife. Amin.

JESU Y’OGBA ELESE
1. Jesu y’o gba elese
Kede re fun gbogb’eda
Awon ti won sako lo
Awon ti won ti subu
Ko l’orin, ko si tun ko
Kristi ngba’awon elese
Fi oto na ye won pe
Kristi ngb’awon elese
2. Wa, y’o fun o ni ‘simi
Gbagbo, oro Re daju
Y’o gba eni buru ju
Kristi ngb’awon elese
3. Okan mi da mi lare
Mo mo niwaju ofin
Eni t’O ti we mi mo
Ti san gbogbo gbese mi
4. Kristi ngb’awon elese
An’emi to kun f’ese
O ti so mi di mimo
Mo ba wo ‘joba orun. Amin

E YO N’NU OLUWA, E YO
1. E yo n’nu Oluwa, e yo,
eyin t’okan re se dede
eyin t’o ti yan Oluwa,
le ‘banuje at’aro lo
Eyo! E yo!
E yo n’nu Oluwa, e yo!
E yo! E yo
E yo n’nu Oluwa, e yo!
2. E yo ‘tori On l’Oluwa
L’aye ati l’orun pelu
Oro Re bor’ohun gbogbo
O l’agbara lati gbala
3. ‘Gbat’ e ba nja ija rere,
Ti Ota f’ere bori yin
Ogun Olorun t’e ko ri
Po ju awon ota yin lo
4. B’okunkun tile yi o ka
Pelu isudede gbogbo
Mase je k’okan re damu
Sa gbeke l’Oluwa d’opin
5. E yo n’nu Oluwa, e yo
E korin iyin Re kikan
Fi duru ati ohun ko
Aleluya l’ohun goro. Amin.

A SEGUN ATI AJOGUN NI A JE
1. A segun ati ajogun ni a je,
Nipa eje Kristi a ni isegun
B’Oluwa je tiwa, a ki yo subu
Ko s’ohun to le bori agbara re
Asegun ni wa, nipa eje Jesu
Baba fun wa ni ‘segun, nipa eje Jesu
Eni t’a pa f’elese
Sibe, O wa, O njoba
Awa ju asegun lo
Awa ju asegun lo
2. A nlo l’oruko Olorun Isreal
Lati segun ese at’aisododo
Kise fun wa, sugbon Tire ni iyin
Fun ‘gbala at’isegun ta f’eje ra
3. Eni t’O ba si segun li ao fi fun
Lati je manna to t’orun wa nihin
L’orun yo sig be imo ‘pe asegun
Yo wo ‘so funfun, yo si dade wura. Amin


No comments

Youtube Channel