FALSE

Page Nav

HIDE
GRID_STYLE
FALSE
TRUE

Latest Update:

latest

Adsense

Popular Yoruba Hymns 1

CONTENTS 1. Iwo to few a la o ma sin  2. Okan mi yin Oluwa logo  3. B’oruko Jesu ti dun to  4. Ko su wa lati ma ko orin ti igbani  5. W...

CONTENTS

1. Iwo to few a la o ma sin 
2. Okan mi yin Oluwa logo 
3. B’oruko Jesu ti dun to 
4. Ko su wa lati ma ko orin ti igbani 
5. Wa ba mi gbe 
6. Fi iyin fun Jesu, Olurapada wa 
7. Eje k’a f’inu didun 
8. Emi ‘ba n’egberun ahon 
9. E wole f’oba ologo julo 
10. Gbogbo aye gbe Jesu ga 
11. Okan mi yin Oba orun 
12. Si o Olutunu Orun 
13. Mimo, mimo, mimo olodumare 
14. A f’ope f’Olorun 
15. I gba mi d’owo Re 

Iwo to fe wa la o ma sin

1. I wo to fe wa la o ma sin titi
Oluwa Olore wa
Iwo to n so wa n’nu idanwo aye
Mimo, logo ola re
Baba, iwo l’a o ma sin
Baba, iwo l’a o ma bo
Iwo to fe wa l’a o ma sin titi
Mimo l’ogo ola re.
2. Iwo to nsure s’ohun t’a gbin s’aye
T’aye fi nrohun je o
Awon to mura lati ma s’oto
Won tun nyo n’nu ise re.
3. Iwo to nf’agan lomo to npe ranse
Ninu ola re to ga
Eni t’o ti s’alaileso si dupe
Fun ‘se ogo ola re
4. Eni t’ebi npa le ri ayo ninu
Agbara nla re to ga
Awon to ti nwoju re fun anu
Won tun nyo n’nu ise re.
5. F’alafia re fun ijo re l’aye
K’ore-ofe re ma ga;
k’awon eni tire ko ma yo titi 
ninu ogo ise re. Amin.

Okan mi yin Oluwa logo
1. Okan mi yin Oluwa logo
Oba iyanu t’o wa mi ri
Un o l’agogo iyin y’aye ka
Un o si f’ife atobiju han
Oluwa, open i fun O
Fun ore-ofe t’o fi yan mi
Jowo dimimu titi dopin
Ki nle joba pelu re loke.
2. Bi eranko l’emi ba segbe
Bikose ti oyigiyigi ;
Lairotele l’Emi Mimo de
T’o f’ede titun si mi l’enu.
3. Ayo okan mi ko se rohin
Loro, losan, loganjo oru;
Gbat’Emi Mimo ti de ‘nu mi
Mo nkorin orun lojojumo
4. Jesu ti la mi loju emi
Mo si f’eti gbohun ijinle;
O nse faji ninu okan mi;
Kini mba fi fun Olugbala?
5. Em’o sogo ninu Oluwa
K’emi ma ba di alaimore;
B’o ti pe mi iyanu l’o je;
Awon angeli d’olufe mi.
6. Mo damure lati sin Jesu
Laifotape larin aye yi;
Nibikibi t’oba nto mi si
O daju ko ni jeki ndamu.
7. Bi mba pari ‘re-ije l’aye
Olugbala, ma je ki npofo;
Ni wakati na jeki ngbo pe
Bo sinu ayo ayeraye. Amin.


B’oruko Jesu ti dun to

1. B’oruko Jesu ti dun to,
ogo ni fun Oruko Re
o tan banuje at’ogbe
ogo ni fun oruko Re
ogo f’oko Re, ogo f’oko Re
ogo f’oruko Oluwa
ogo f’oko Re, ogo f’oko Re
ogo f’oruko Oluwa
2. O wo okan to gb’ogbe san
Ogo ni fun oruko Re
Onje ni f’okan t’ebi npa
Ogo ni fun oruko Re
3. O tan aniyan elese,
Ogo ni fun oruko Re
Ofun alare ni simi
Ogo ni fun oruko Re
4. Nje un o royin na f’elese,
ogo ni fun oruko re
Pe mo ti ri Olugbala
Ogo ni fun oruka Re.


Ko su wa lati ma ko orin ti igbani
1. Ko su wa lati ma ko orin ti igbani
Ogo f’olorun Aleluya
A le fi igbagbo korin na s’oke kikan
Ogo f’olorun, Aleluya!
Omo olorun ni eto lati ma bu s’ayo
Pe ona yi nye wa si,
Okan wa ns’aferi Re
Nigb’o se a o de afin Oba wa ologo,
Ogo f’olorun, Aleluya!
2. Awa mbe n’nu ibu ife t’o ra wa pada,
ogo f’olorun Aleluya!
Awa y’o fi iye goke lo s’oke orun
Ogo f’olorun, Aleluya!
3. Awa nlo si afin kan ti a fi wura ko,
ogo f’olorun Aleluya!
Nibiti a ori Oba ogo n’nu ewa Re
Ogo f’olorun, Aleluya!
4. Nibe ao korin titun t’anu t’o da wa nde
Ogo f’olorun Aleluya!
Nibe awon ayanfe yo korin ‚yin ti Krist;
Ogo f’olorun, Aleluya!. Amin


WA BA MI GBE
1. Wa ba mi gbe, ale fere le tan
Okunkun nsu, Oluwa ba mi gbe;
Bi oluranlowo miran ba ye
Iranwo alaini, wa ba mi gbe
2. Ojo aye mi nsare lo s’opin
Ayo aye nku, ogo re nwomi
Ayida at’ibaje ni mo n ri
‘wo ti ki yipada, wa ba mi gbe
3. Ma wa l’eru b’Oba awon oba
B’oninure, wa pelu ‘wosan Re?
Ki Ossi ma kanu fun egbe mi
Wa, ore elese, wa ba mi gbe.
4. Mo nfe O ri, ni wakati gbogbo
Kilo le swgun esu b’ore Re?
Tal’o le se amona mi bi Re?
N’nu ‘banuje at’ayo ba mi gbe
5. Pelu ‘bukun Re, eru ko ba mi
Ibi ko wuwo, ekun ko koro,
oro iku da? ‚segun isa da?
Un o segun sibe, b’iwo ba mi gbe.
6. Wa ba mi gbe, ni wakati iku,
Se ‘mole mi, si toka si orun
B’aye ti nkoja, k’ile orun mo
Ni yiye, ni kiku, wa ba mi gbe. Amin.


FI IYIN FUN JESU OLURAPADA WA

1. Fi iyin fun Jesu, Olurapada wa,
Ki aye k’okiki ife Re nla ;
Fi iyin fun ! eyin Angeli ologo,
F’ola at’ogo fun oruko re,
B’olu’agutan, Jesu y’o to omo Re
L’apa Re l’o ngbe won le l’ojojo
Eyin eniyan mimo ti ngb’oke Sion
Fi iyin fun pelu orin ayo
2. Fi iyin fun, Jesu Olurapada wa,
Fun wa, O t’eje Re sile, O ku
On ni apata, ati reti ‘gbala wa,
Yin Jesu ti a kan m’agbelebu;
Olugbala t’O f’ara da irora nla
Ti a fi ade egun de lori
Eniti a pa nitori awa eda
Oba ogo njoba titi laelae.
3. Fi iyin fun, Jesu Olurapada wa
Ki ariwo iyin gba orun kan
Jesu Oluwa njoba lae ati laelae,
Se l’oba gbogb’eyin alagbara
A segun iku; fi ayo royin na ka
Isegun re ha da, isa oku?
Jesu ye ko tun si wahala fun wa mo
‘tori O l’agbara lati gbala. Amin.

E JE J’A F’INU DIDUN
1. Eje k’a f’inu didun
Yin Oluwa Olore
Anu Re O wa titi
Lododo dajudaju
2. On nipa agbara Re
F’imole s’aye titun
Anu Re, O wa titi
Lododo dajudaju
3. O mbo gbogb’eda ‘laye
O npese fun aini won
Anu re, O wa titi
Lododo dajudaju
4. O bukun ayanfe Re
Li aginju iparun
Anu re O wa titi
Lododo dajudaju
5. E je k’a f’inu didun
Yin Oluwa Olore
Anu Re, O wa titi
Lododo dajudaju. Amin.

EMI ‘BA N’EGBERUN AHON
1. E mi ‘ba n’egberun ahon,
Fun ‘yin Olugbala
Ogo Olorun Oba mi
Isegun Ore Re.
2. Jesu t’o seru wa d’ayo
T’o mu banuje tan
Orin ni l’eti elese
Iye at’ilera.
3. O segun agbara ese
O da onde sile
Eje Re le w’eleri mo
Eje Re le w’eleri mo
Eje Re seun fun mi
4. O soro, oku gb’ohun Re
O gba emi titun ;
O niro binuje je y’ayo
Otosi si gbagbo
5. Odi, e korin iyin re
Aditi , gbohun Re
Afoju, Olugbala de, 
Ayaro, fo f’ayo
6. Baba mi at’olorun mi,
Fun mi ni ‘ranwo Re
Ki nle ro ka gbogbo aye
Ola oruko Re. Amin.

E WOLE F’OBA, OLOGO JULO
1. E wole f’oba, Ologo julo
E korin ipa ati ife Re
Alabo wa ni at’eni igbani
O ngbe ‘nu ogo, Eleru ni iyin
2. E so t’ipa Re, e so t’ore Re
‘mole l’aso Re, gobi Re orun
Ara ti nsan ni keke ‘binu Re je
Ipa ona Re ni a ko si le mo
3. Aye yi pelu ekun ‘yanu Re
Olorun agbara Re l’oda won
O fi id ire mule, ko si le yi
O si f’okan se aso igunwa Re.
4. Enu ha le so ti itoju Re ?
Ninu afefe ninu imole
Itoju Re wa nin’odo ti o nsan
O si wa ninu iri ati ojo
5. Awa erupe aw’alailera
‘wo l’a gbekele, o ki o da ni
Anu Re rorun o si le de opin
Eleda, Alabo, Olugbala wa
6. ‘wo Alagbara Onife julo
B’awon angeli ti nyin O loke
Be l’awa eda Re, niwon t’a le se
A o ma juba Re, a o ma yin O. Amin.

GBOGBO AYE , GBE JESU GA
1. Gbogbo aye, gbe Jesu ga,
Angel’, e wole fun
E mu ade Oba Re wa,
Se l’Oba awon oba
2. E se l’Oba eyin Martyr,
Ti npe ni pepe Re
Gbe gbongbo igi Jese ga
Se l’Oba awon oba
3. Eyin iru omo Isreal’
Ti a ti rapada
E ki Eni t’ogba yin la
Se l’Oba awon oba
4. Gbogbo eniyan elese
Ranti ‘banuje yin
E te ‘kogun yin s’ese Re
Se l’Oba awon oba
5. Ki gbogbo orile ede
Ni gbogbo agbaye
Ki won ki, « Kabiyesile »
Se l’Oba awon oba
6. A ba le pel’awon t’orun
Lati ma juba Re
K’a bale jo jumo korin
Se l’Oba awon oba. Amin.

Okan mi yin Oba orun
1. Okan mi yin Oba orun
Mu ore wa sodo re
‘Wo ta wosan, t’a dariji
Tal’aba ha yin bi Re ?
Yin Oluwa, yin Oluwa
Yin Oba ainipekun
2. Yin fun anu t’o ti fi han
F’awon Baba ‘nu ponju
Yin L Okan na ni titi
O lora lati binu
Yin Oluwa, yin Oluwa
Ologo n’u otito
3. Bi baba ni O ntoju wa
O si mo ailera wa
Jeje l’o ngbe wa lapa Re
O gba wa lowo ota
Yin Oluwa, yin Oluwa
Anu Re, yi aye ka
4. Angel, e jumo ba wa bo
Eyin nri lojukoju
Orun, Osupa, e wole
Ati gbogbo agbaye
E ba wa yin, e ba wa yin
Olorun Olotito. Amin.

SI O OLUTUNU ORUN
1. Si o Olutunu Orun
Fun ore at’agbara Re
A nko, Aleluya
2. Si O, ife eni t’Owa
Ninu Majemu Olorun
A nko, Aleluya
3. Si O agbara Eni ti
O nwe ni mo, t’o nwo ni san
A nko, Aleluya
4. Si O, Oluko at’ore
Amona wa toto d’opin
A nko, Aleluya.
5. Si O, Eniti Kristi ran
Ade on gbogbo ebun re
A nko, Aleluya. Amin.

MIMO, MIMO, MIMO, OLODUMARE

1. Mimo, mimo,mimo, Olodumare
Ni kutukutu n’iwo O gbo orin wa
Mimo, mimo, mimo ! Oniyonu julo
Ologo meta, lae Olubukun
2. Mimo, mimo, mimo ! awon t’orun nyin
Won nfi ade wura won le ‘le yi ‘te ka
Kerubim, serafim nwole niwaju Re
Wo t’o ti wa, t’O si wa titi lae.
3. Mimo, mimo,mimo ! b’okunkun pa o mo
Bi oju elese ko le ri ogo re
Iwo nikan l’O mo, ko tun s’elomiran
Pipe ‘nu agbara ati n’ife.
4. Mimo, mimo, mimo ! Olodumare
Gbogbo ise Re n’ile l’oke l’o nyin O
Mimo, mimo, mimo ! Oniyonu julo
Ologo meta lae Olubunkun ! Amin.

A F’OPE F’OLORUN
1. A f’ope f’olorun
L’okan ati l’ohun wa
Eni s’ohun ‘yanu
N’nu eni t’araye nyo
‘gbat’a wa l’om’owo
On na l’o ntoju wa
O si nf’ebun ife
Se ‘toju wa sibe.
2. Oba Onib’ore
Ma fi w asile laelae
Ayo ti ko l’opin
On ‘bukun y’o je ti wa
Pa wa mo n’nu ore
To wa, gb’a ba damu
Yo wa ninu ibi
L’aye ati l’orun
3. K’a f’iyin on ope
F’Olorun, Baba, Omo
Ati Emi mimo
Ti O ga julo lorun
Olorun kan laelae
T’aye at’orun mbo
Be l’o wa d’isiyi
Beni y’o wa laelae.

Igba Mi d’owo Re
1. I gba mi d’owo Re
Mo fe k’O wa nibe
Mo f’ara, ore, emi mi
Si abe iso Re
2. Igba mi d’owo Re
Eyi t’o wu k’o je
Didun ni tabi kikoro
B’O ba ti ri p’o to.
3. Igba mi d’owo Re
Emi y’o se beru ?
Sokun li ainidi
4. Igba mi d’owo Re
Jesu t’a kan mo ‘gi
Owo na t’ese mi dalu
Wa di alabo mi
5. Igba mi d’owo Re
‘wo ni ngo gbekele
Leyin iku, low’otun Re
L’em’o wa titi lae. Amin.

No comments

Youtube Channel